Intro
Aahaa , aaaa, eba…
bee ni, Ifeto somo bibi lafe soro nipa,
dokita ti en wo Yen o feto si,
iyalode ti e n ri Yen o feto si,
Alufa wa gan ko owun na feto si.
oya eteti ke gbo.
Verse 1
Oko to ba soji ati aya to damo,
Won a jo too o, kole jorawon.
Oko to se ke aya, o ma gbo ti aya.
Aya toba se ike oko, oma gbo toko.
Agbajowo ni a lefi sanya oh.
Owo kan lasan kole gberu dori oh.
Oju teri yen ni alankan fi’n sori oh
Je ki ajo too, kole jara won.
Lead: Bobo too oh,
Resp: Kole jorawon.
Lead: Sisi too oh,
Resp:Kole jorawon.
Lead: Ebi e too oh,
Resp: Kole Jorawon.
Lead: Ore too oh,
Resp: Kole jorawon.
Lead: Ara e too oh,
Resp: Kole jorawon
Chorus
Feto si oh oh oh(3 times)
Feto somo bibi.
Verse 2 (Rap)
Baba mama e egbo ohun ti mo fe wi.
Ati omode ati agbalagba gbogbo wa lo bawi.
Ni pase ifeto somo bibi.
Awa lodomode olorin to n korin ogbon.
Eni to jin si koto, ko ara yoku logbon.
Arale, mo ni ke gbayi kogbon.
Gbogbo omo to n be lara mi, on mo ma bi tan.
Mofe fi jo baba baba mi ti mo gbo ninu itan.
Omo Bere osi Bere lo n fa.
Ma tori igbadun iseju marun, to fe fi yoofa,
ke wa bi won sile tan, ke je ki won ma jiya.
Eru to le dagbe, to sope o fe owo fa.
oni to ba bimo mejila o ma bi mefa.
Gbogbo egbe e ti se nkan, iwo sore di olufa.
Abo oro o to fun omoluabi, to ba de inu e se lo ma di odidi.
Toko taya, ka fowo sowo po.
kari eni bani so oto oro, ko wopo.
To gbogbo e papo, kajo too.
Lati ojule si ojule, titi de ileto.
Chorus
Feto si oh oh oh(3 times)
Feto somo bibi.
Outro
seti jasi bayi?
Ifeto somo bibi se pataki gan.
kiya kiya e tete ki e lo feto si.
too gbogbo e papo kajo too oooo.